Àjọ Aláalánú Ọmọnìyàn, ti Olusẹgun Ọbasanjo , ní Ọjọ́bọ̀, bẹ̀rẹ̀ pínpín ohun èlò ìlera fún àwọn tí ó ní ìpèníjà gbígbọ́ ọ̀rọ̀ jákè-jádò Gúsù Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Àjọ Olusẹgun Ọbasanjo pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba Ìpínlẹ̀ Abia, Àjọ Aláàánú Ọmọnìyàn Starkey, ni ó se agbátẹrù ètò náà
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò náà, Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí Ọbasanjọ sàpèjúwe àwọn ohun èlò ìgbọrọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun èlò tí yóò mú ìyàtọ̀ olóore bá àwọn tí ó ní ìpèníjà náà, tí yóò sì sọ ìgbé ayé wọn di ọ̀tun. Ó tẹ̀síwájú pé àjọ náà ní àfojúsùn ìpèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́, ètò ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ètò ìlera tí ó gún régé, àtipé ní pàtàkì jùlọ síṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó ní ìpèníjà ìgbọ́rọ̀.