Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Àṣà Kí Àlàáfín Tuntun Ti Ìlú Ọ̀yọ́ Kú Oríire

385

 

Mínísita orílè-èdè yìí fún àṣà, iṣẹ, Ìrìn-àjò òun igbafe àti ọgbọ́n àtinúdá ọrọ̀ ajé, Hannatu Musawa ti kí Àlàáfín tuntun ti Ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Abimbola Akeem Owoade, kú oríire, ti ìgorí ìtẹ́ baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Aláàfin ìkẹrìndínláàdọ̀ta.

 

Ó gbàdúrà fún ọba fún ọgbọ́n àti ẹ̀mí gígùn àti ìṣèjọba tó léso rere lórí ìtẹ́.

 

”Awa láti mínísirì, àṣà, iṣẹ, Ìrìn-àjò òun igbafe àti ọgbọn àtinúdá ọrọ̀ ajé jẹ̀jẹ́ atilẹyin àti àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọba àti àwọn ènìyàn rere ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti gbé
àṣà Nàìjíríà lárugẹ, kí a má jẹ́ kí ó kú, ki a si tun ri pé ìṣọ̀kan wà láàrin wà, Mínísita Musawa sọ èyí”.

 

”ki Ọlọ́run fún Aláàfin ní aláafia, ọgbọ́n àti ìtọ́ni ti yóò fi darí àwọn ènìyàn rẹ bí o ṣe gorí ìtẹ́, a ń fi ojú sọ́nà fún ìbásisẹ́pọ̀ to dan mọ́rán pẹ̀lú ọba láti mú kí àṣà, ọgbọ́n àtinúdá ilé iṣẹ́ orílẹ̀-èdè yìí tẹ̀síwájú”.

 

Musawa fi bí inú rẹ ti dun hàn , ó si ki ọba alayé náà ku oríire .

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button