Gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí Nàìjíríà, Steve Crown ti kéde ìròyìn ayọ̀ fáráyé gbõ pé òun ti ri ìyàwó, Ruth Thomas.
Àwọn méjèèjì ti wọn ti jọ ń ṣe ọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ fún ìgbà díẹ kan ti wá kéde ọjó kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin , ọdún 2025 gẹ́gẹ́bí ọjọ́ ìgbéyàwó wọn.
Steve crown fi léde lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram níbi tó ti ṣe àfihàn fídíò ètò Igbeyawo rẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà.
” Olúwa fi àṣẹ sí i, a o jọ wà títí láyé”, ó kọọ́ báyìí – #CrowningRuth2025. 26th APRIL 2025.”
Eléyìí ti jẹ ìròyìn ayọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ pàápàá jù lẹ́ka orin ti ẹ̀mí bíi;
Judikay, Eben, Yadah, Okopi Peterson, Joe Praize, àti Ada Ehi, gbogbo wọ́n sì ti rán iṣẹ́ ayọ̀ síi kí Ọlọ́run mú ọjọ́ ró.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san