Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu dárò ikú Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ nígbà kan rí, Olunloyo

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

78

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti ṣèdárò pẹ̀lú ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo lórí ikú Dókítà Victor Omololu Olunloyo, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ àtijọ́ nígbà kan rí.

Ààrẹ Tinubu, ni orukọ Ijọba Apapọ, ti kẹdun pẹlu ẹbi Olunloyo ati awọn ti o mọọ ti o si pọn agba ilu ati ọjọgbọn naa le.

Nigba ti o n sọrọ lori saa Dokita Olunloyo bii Gomina ipinlẹ Ọyọ atijọ, Aarẹ Tinubu sọ pe, Asiko to lo lori oye ko pẹ, ṣugbọn asiko rẹ ni afoju sun ati idari ti ko lẹlẹgbẹ. Bi awọn ologun ṣe mu ijọba rẹ wa si opin lairo tẹlẹ ko tun di lọwọ lati tẹ siwaju ni sinsin orilẹ-ede.”

Ifiranṣẹ ikẹdun rẹ si ẹbi ati ijọba ipinlẹ Ọyọ tun gboriyin fun Gomina nigba kan naa ri fun afisọkan rẹ si Iṣọkan,idagbasoke, ati ilọsiwaju ọgbọn Naijiria, wipe awọn ipa ti o ko yoo maa jẹ amin to nipa ninu itan orilẹ-ede.

Ààrẹ Tinubu wa pari idaro rẹ pẹlu adura, ti o si n bẹ ọlọrun ko tẹ olunloyo safẹfẹ rere ki o si rọ awọn ti n ṣedaro lẹyin rẹ loju.

Comments are closed.

button