Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ ọmọ ilé àwọn tí kò pọ̀ bẹnu àtẹ́ lu Ìpànìyàn tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Edo

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

98

Ẹgbẹ́ ọmọ ilé Aṣojú ti àwọn tí kò pọ̀, ti bẹnu àtẹ́ lu bí ẹgbẹ́ oníjàgídíjàgan kan ní ìpínlẹ̀ Ẹdo ṣe ṣekú pa àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò dín ní mẹ́rìndín-lógún, tí àwọn ọmọ bíbí inú Arewa pọ̀jù lọ nínú wọn, ní ọjọ́ kejìdín-lọ́gbọ̀n, oṣù kẹta.

Ibẹnuatẹlu yii wa ninu alaye kan ti adari ẹgbẹ awọn ti ko pọ, Ọgbẹni Kingsley Chinda ati awọn adari ẹgbẹ awọn ti ko pọ miiran buwọ lu, ní Abuja.

Ẹgbẹ naa tun wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa da idajọ oju ẹsẹ fun awọn ara ilu ẹgbẹ wọn, ki wọn maa pe awọn agbofinro nigba ti wọn ba ti ri awọn iṣe to ruwọn loju.

Orilẹ-ede wa lofin, awọn ile iṣẹ agbofinro wa naa si ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo ọmọ Naijiria lati jẹ ipe wọn.

O tun wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣe jẹjẹ, wa lalaaafia, ki wọn o tẹle ofin ki wọn o si jẹ ki Naijiria ati awọn ijọba ipinlẹ  ṣe iwadi ọrọ naa, ki wọn le mọdi ododo.

 “A wa ba awọn ẹbi awọn oloogbe kẹdun ti o si tun n fi dawọn ati awọn ọmọ Naijiria loju pe, awa, ẹgbẹ awọn ti ko pọ ni ile Aṣoju, yoo maa woye titi ododo ọrọ naa yoo fi foju han,” O fi kun un.

Comments are closed.

button