Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Ọmọogun Ba Ìmọ̀ Àwọn Ajínigbé Jẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Taraba

210

 

Ikọ̀ ọmọ ogún ọ̀wọ́ kẹfà orílẹ̀-èdè yìí – 6 Brigade Nigerian Army and Sector 3 Operation Whirl Stroke (OPWS) ti bá ìmọ̀ awon Ajínigbé jẹ́ ní ojú ọ̀nà Takum-Jalingo, ipinlẹ Taraba Àríwá ìlà oòrùn Nàìjíríà.

 

Ikọ̀ àwọn ọmọ ogún náà gbéra kíá nigba ti wọn gbọ́ ìpè, wọn si bá àwọn ajinigbe náà fìjà pẹ́ẹ̀ta pẹlu ìró ibọn kẹ̀ù kẹ̀ù ti wọn sì fi tipátipá gba ondè wọn sílẹ, àwọn ẹni ti wọn gba sílẹ lọwọ wọn ní ọgbẹni Yakubu Usman àti ọgbẹni Godwin Peter. Wọ́n si ti gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

 

Bí ọ̀gagun àgbà Oni sé sọ, àwọn ọmọ ogún àti àwọn Ọlọ́pàá duro wámúwámú sì Santa wọn sì bá ìmọ àwọn ajinigbe náà jẹ ní ìlú Muji. O sọ síwájú pé àwọn ọmọ ogun wà fún ìdóòlà ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn ní ìpínlẹ̀ Taraba àti káàkiri Naijiria.

Ó wá rọ àwọn ènìyàn láti tètè máa pèsè ìròyìn ti yóò ràn wọ́n lọwọ láti gbógun ti àwọn Ọ̀daràn láwùjọ.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button