Kò dín ní ẹgbẹ̀rún ènìyàn nínú àwọn olùgbé àgbègbè Boro Pit, Calabar, Ipinlẹ Cross River tí ó jẹ ànfààní ìwòsàn ọ̀fẹ́ èyí tí Àjọ Ọmọ Ogun se agbátẹrù rẹ̀
Ètò ìlera náà, èyí tí ó máa ń wáyé ní ìgbà mẹ́rin nínú ọdún kan níbi tí àyẹ̀wò àti ìtọ́jú oníran-ìran ìwòsàn ti máa n wáyé
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun lásìkò ètò náà, ọ̀gágun Ajọmale Oride sọ pé ètò náà wáyé láti se àtìlẹyìn fún àwọn ènìyàn, àtipé Ọ̀ga Àgbà Àjọ Ọmọ Ogun Ojú Omi, Ọ̀gágun Emmanuel Ogalla ni ó pàsẹ síṣe àgbékalẹ̀ ètò náà