Omidan Felicia Ogbonna, tí ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba léyìí tí ó bèrè fún ìdájọ́ òdodo látàrí fífi ipá bá a lòpọ̀, èyí tí ó wáyé láti ọwọ́ onísòwò ńlá tí ó fi ìlú Èkó se ibùgbé, Ọ̀gbẹ́ni Emeka Uyalemuo
Ọ̀gbẹ́ni Martin Agba tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀ ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní ìlú Abuja ní ọjọ́ Ẹtì, nígbà tí ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn sọ pé afurasí náà ti bá òun lòpọ̀ ní àìmọye ìgbà léyìí tí ìyàwó rẹ̀ náà jẹ́ olùjẹ́rìí sí i
Nígbà tí ó ń fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn láti ẹnu agbẹjọ́rò rẹ̀, Felicia sọ pé ìsẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2021 nígbà tí òun wà ní ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún, tí òun sì ń gbé pẹ̀lú ìdílé Uyalemuo, ní ìlú Èkó
Ó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àpapọ̀ àti gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu láti rí i dájú pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ìsẹ̀lẹ̀ láabi náà