Take a fresh look at your lifestyle.

Oníṣẹ́ Ọnà Ké Gbàjarì Pé Isẹ́ Ọnà Àti Àṣà Wa Kò Gbọdọ̀ Parun

303

Oníṣẹ́ ọnà kan ní orílẹ̀-èdè yìí, Isah Lawan, ti ke gbajari sì àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí pé isé ọnà àti àṣà wa ti fẹ máa lọ sì oko ìparun.

Ọgbẹni Lawani ti o ti wá nidi isẹ́ ọnà láti bi ogójì ọdún sẹyìn, ẹni ti o n sisẹ́ ní Eko Hotel and Suites Art and Crafts Centre ti fi àìdunnú rẹ hàn pé iṣé ọnà àti àṣà wà ti nlọ sì oko ìparun nígbà ti ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀.

” Ki a ma purọ́, àwọn àrè fẹràn isẹ́ ọnà wa ju àwa ọmọ orílẹ̀-èdè yìí lọ”. Nibi ti a bá ti ri ènìyàn bíi ogójì sí àádọta aláwọ̀ funfun tó wá wo ọjà wa wò tí ọgbọ̀n nínú wọn sì bawa ra, tipátipá ní a fi máa ri ọmọ Nàìjíríà kan soso ti yóò bawa wo igbá. A kò nífẹ̀ẹ́ síi rárá., ” Ó sọ èyí.

O sọ pé eyi ríbẹ̀ latari àìníẹ̀ẹ́ sì nǹkan àṣà mọ́ nípa yíyọ ẹ̀kọ́ ìtàn àti ẹ̀kọ́ nípa isẹ́ ọnà kúrò ninú ẹ̀kọ́ wà ní àwọn ilé ìwé wa.

Lawan tún fi kun pe àwọn ilé kọọkan ti wọ́n ti ń pọnlé tẹlẹ náà ti fi silẹ wipe isẹ́ Èṣù ní látàrí ìgbàgbọ wọn.

” Sugbon lai f’ọta pé , a fẹ fi àwọn Iṣẹ ọnà yìí pamọ́ dé àwọn ọmọ wà, láti mọ isé ọnà náà, orúkọ rẹ, ibi ti o ti wá.” o sọ eyi.

O wà pé àwọn èèkàn pàápàá jù ìjọba kí wọn sọ ayẹyẹ ọnà àti asa jí bíi – 1977 Festival of Arts and Culture (FESTAC ’77).

O tún pé fún àpèpadà àbẹwò ọlọlá- sì isé ọnà àti àṣà wa láti ọdọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
”Ti a Ko ba tete gbé ìgbésẹ báyìí, ìtàn wa a di ìgbàgbé,” o ké gbàjarì. O wà pé àwọn èèkàn pàtàkì láti gbé ẹ̀kọ́ àṣà wà larugẹ, kéde ìtanijí , kí wọ́n sì ṣe ètò tó faramọ́ orísun ẹwà isẹ́ ọnà àti àṣà orílè-èdè yìí láti má jè kó parun.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button