Àjọ Actors Guild of Nigeria (AGN), ti gbosuba ràbàndẹ̀ fún ijọba Plateau fun akitiyan rẹ ninu ìtesiwaju Ilé Iṣẹ Sinimọ.
Akọ̀wé apapọ àjọ náà, ọgbẹni Abubakar Yakubu, sọ pé akitiyan ìjọba Plateau kò ṣe fi ọwọ́ rọ sẹ́yìn nínú ìdàgbàsókè Ilé Iṣẹ Simimọ́ ní Nàìjíríà.
Yakubu sọ pé ọpọ ẹka fíìmù ti wọn yà ní ìpínlẹ̀ Plateau lo dára púpọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ilé iṣẹ fíìmù láti ọdún 1960 o lé díẹ̀.
Alága Kọmiti elétò ìdìbò tó tún jẹ ogbontarigi ninu isẹ náà, Ọ̀gbẹ́ni Sunday Apkome BJ tirẹ sọ pe àwọn òṣeré tọ ṣẹṣẹ ní dide ní ìpínlè náà ní láti lo ànfààní wíwà Nigerian Film Corporation (NFC) ati the Film Institute (NFI) láti tètè lọ kekọ̀ọ́ níbẹ̀.
Oníròyìn roo pé àwọn tó wà níbí ayẹyẹ náà ní olóyè Seigha Ebide,
Akọ́wọ́rìn pẹ̀lú Gómìnà Caleb Mutfwang, to jẹ ọkan lára àwọn alabojuto nígbà ètò ìdìbò.
Àwọn oníròyìn tún sọ pé àwọn òṣeré lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló kópa níbi ètò idibo wọn ní ẹ̀ka jẹ̀ka tó wáyé.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san