Quadri Aruna ti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin lórí tábìlì tó dára jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ báyìí, ó sún sí ipò kejìdínlógún lágbáyé.
Ó ti síwájú ọmọ orílẹ̀-èdè Egípítì, Omar Assar láti jẹ́ ẹni tó dara jùlọ nínú bọ́ọ̀lù gbígbá ẹlẹ́yin lórí tábìlì tó dára jùlọ ní ilé Adúláwọ̀ báyìí níbi òṣùwọ̀n ITTF ti wọ́n gbé jáde ní ọjó Ìṣẹ́gun. Aruna tó wà ní ipò kọkàndínlógún tẹ́lẹ̀ ti wá bọ́ sì ipò kejìdínlógún nígbàtí Assar yọ̀ tẹ̀rẹ́ láti ipò kẹtàdínlógún sì ipò kọkàndínlógún.
Ìdojúkọ Míràn Tó Ń Bọ̀ Fún Aruna
Aruna yóò tún ní ìfagagbága ní ìdíje WTT Contender Chennai ni India, ti yóò wáyé ní ọjó kẹtàlélógún sí Ọgbọnjọ́. Ìsesí rẹ̀ nínú ìdíje náà tún leè jẹ́ kó tẹ̀wọ̀n síi lágbayé,
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san