Àjọ African Development Bank Afdb ti gbin ọrọ Ajé Mílíọ̀nù Méjọ nípa ti ohun èèlò Omi káàkiri ogójì Ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti ọdún 2020, ti yóò wúlò fún àwon èniyàn tó jù méjìléàádọ̀rún mílíọ̀nù.
Adarí àjọ Water Development and Sanitation Department, AfDB, Ọ̀gbẹ́ni Johannes Chirwa, ló sọ èyí ni ibi ìpàdé African Ministers’ Council on Water (AMCOW), ti agbègbè ìwọ̀ òòrùn Adúláwọ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní ìlú Abuja.
Emily Kilongi ló ṣe oluduro fún Chirwa, onímọ̀ ẹrọ àgbà àjọ AfDB- Principal Water and Sanitation Engineer of AFDB.
Ó sọ pé ìpàdé náà jè òòrè ọfẹ pàtàkì láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò ìtèsíwájú, ìborí ìṣòro àti ọ̀nà àriwá àbáyọ sì ọgbọ́n àtinúdá ìtèsíwájú fún ètò ìdarí omi ni ilẹ̀ Áfríkà.
Wọ́n dá àjọ AMCO sílẹ̀ ní ọdún 2002 fún ìtèsíwájú àjọṣepọ̀, ètò ààbò, ìtẹ̀síwájú ọrọ̀ ajé nípasẹ̀ ètò ìdarí ọrọ̀ omi àti ètò ìgbékáàkiri rẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san