Ààrẹ fún ẹgbẹ́ PMAN ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Ọ̀gbẹni Pretty Okafor ti so èròngbà ẹgbẹ́ láti túbọ̀ mú ilé iṣé amóhùnmáwòrán àti Radio gbórò sí ni ilu Abuja.
Ó sọ èyí di mímọ̀ ni ọjọ́ Ìṣẹgun ni ìlú Abuja nigba tí o n mú àwọn àlejò rẹ káàkiri àwọn agbègbè ilé iṣé náà àti ẹgbẹ́ NEC.
Ó ní ilé iṣé PMAN ti o wá ni Kukwabe yóò jẹ okan lára málegbagbè ilé iṣé Amóunmáwòrán àti Radio ti àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò fi ma ṣe àpèjúwe réré.
Ó wa ṣe àpèjúwe ní ẹka ìdáranilaraya gẹgẹ bí ẹka ti o ṣe pàtàkì jùlọ láwùjọ.