Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ NAFDAC Sèkìlọ̀ Fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Jìnà Sí Ọtí Àmupara

122

Àjọ NAFDAC ti sèkìlọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ewu tí ó wà níbi ọtí àmujù àti lílo òògùn ní ìlòkulò

 

Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisọla Adeyẹye tí ó jẹ́ alákòsóo àjọ náà ni ó sèkìlọ̀ níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ti o wáyé fun àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onípele kejì ní ọjọ́ Àbámẹ́ta

 

Adeyẹye, ẹnití Arábìnrin Harirah Abdullahi sojú fún sàfirinlẹ̀ pàtàkì ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, ó baníjẹ́ lórí bí àwọn ògo wẹẹrẹ se ń lo òògùn ní ìlòkulò ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

 

Ètò náà wáyé ní ilé ìwé onípele kejì tí ó wà ní Kamfanin Bobi ati Ma’azu Ibrahim, ni ìlú Kontagora, níbi tí ó ti sèkìlọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ láti jìnà sí àsìlò òògùn ki wọn si mu idagbasoke ọjọ iwaju wọn ni ọ̀kúkúdùn

 

 

Comments are closed.

button