Ààrẹ Ẹgbẹ́ Òsìṣẹ́, Ọ̀gbẹ́ni Joe Ajero ti pàrọwà sí ìjọba àti àwọn ẹlẹ́sìn gbogbo láti gbé ìgbésẹ̀ èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ètò ìlera ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ajero sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń sí ilé ìwòsàn èyí tí ìjọ ẹlẹ́sìn kan se àgbékalẹ̀ rẹ̀ ní àgbègbè Piwoyi, Ìlú Abuja
Ó gbósùbà fún alàgbà Ìjọ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Musa fun àseyọrí ńlá tí ó wáyé láti ọwọ́ ìjọ Ọlọ́run náà, èyí tí ó wà fún àmúlò àti ìtọ́jú ọmọnìyàn. Ó wá rọ ìjọ ẹlẹ́sìn gbogbo láti kọ́se irúfẹ́ ìwà rere bẹ́ẹ̀ fún ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn lápapọ̀