Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó Dárò Olóògbé Pa Ayọ̀ Adébánjọ Wọ́n Sàpèjúwe Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Akíkanjú

154

 

Wọ́n ti ṣàpèjúwe ikú Olóògbé Ayọ̀délé Adébánjọ gẹ́gẹ́ bí àdánù ńlá fún ìran Yorùbá, nítorí pé, gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ló fi sin ẹ̀yà náà.

Nínú èsì wọn sí ikú Akíkanjú, Olórí Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re náà, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó nínú àtẹ̀jáde wọn, tí Alága Ìgbìmọ̀ fún Ètò Ìròyìn, Ọgbọ́n-ìṣèlú àti Ètò Ààbò ìlú nínú Ilé Aṣòfin náà, Aṣòfin Stephen Ògúndìpẹ́ fọwọ́ sí, ó ṣàpèjúwe Olóògbé Olóyè Adébánjọ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn ‘Awo’ tòótọ́, tí ó jẹ́ ẹni tí ó ń wá ìlọsíwájú ìlú, àti ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tòótọ́.

Ilé Aṣòfin náà mẹ́nu ba àwọn akitiyan rẹ̀ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Òṣèlú ‘Action Group (AG)’ àti United Party of Nigeria (UPN) ìgbà náà lábẹ́ Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀. Wọ́n ní, agbo òṣèlú kò ní gbàgbé rẹ̀, nítorí ṣàṣà ní nǹkan ìdàgbàsókè ìlú tí kì í dá sí.

Aṣòfin Ògúndípẹ̀ sọ pé, “lórúkọ Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mojísọ́lá Lasbat Meranda, a kí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, ìdílé Olóògbé Adébánjọ, àwọn tó ń wá ìlọsíwájú káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kú aráfẹ́rakù ti Olóògbé Olóyè Adébánjọ, kí Olódùmarè tú gbogbo wọn nínú fún àdánù yìí “.

Lánre Lágada-Àbáyọ̀mí

Comments are closed.

button