Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó tí rọ Gómìnà Babajide Sanwo-Olu, àti àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba tọ́ rọ̀ kàn gbogbo láti mú Ìdàgbàsókè bá ayẹyẹ onífàájì ìparí ọdún, tí wọ́n pè ní’ Detty December’, kí ó lè di ayẹyẹ ìlú tí àwọn ará ìlú yóò gbárùkù tì.
Aṣòfin Desmond Elliot tó ń ṣojú àgbègbè Surulere kìíní nínú Ilé Aṣòfin náà ló mú àbá yìí wá nínú àbájáde ìròyìn kan pé, owó tí àwọn ilé ìtura rí nínú ayẹyẹ onífàájì ti ọdún 2024 rí tó Mílíọ̀nù mẹ́rin lé lógójì owó dọ́là, nígbà tí àwọn Oníléeṣẹ̀ fífi ohun èlò yá rí bí mílíọ̀nù mẹ́tàlá owó dọ́là, tí gbogbo rẹ̀ ń lọ bí Mílíọ̀nù mọ́kàléláàdọ́rin ààbọ̀ owó dọ́là ($71.6).
Aṣòfin Gbọ́láhàn Yishawu wòye pé, gbogbo ohun ìdàgbàsókè tó yẹ ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní tí wọ́n fi lè mú Ìgbèrú bá ayẹyẹ yìí. Ó wá pè fún níní ìlàkàlẹ̀ àsìkò tí ayẹyẹ ìrìn-àjò afẹ́ náà yóò máa wáyé lọ́dọọdún.
Aṣòfin Abíọ́dún Tọ̀bùn wòye pé, ayẹyẹ ‘Detty December’ yóò ṣàdínkù ìwà ọ̀daràn láwùjọ nítorí ọ̀pọ̀ àwọn tó lè máà hùwà ibi yìí ni wọn yóò fún níṣẹ́ kan tàbí òmíràn láti ṣe nínú ayẹyẹ náà.
Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mojisola Meranda wá sọ sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ilé Aṣòfin náà pé, wọ́n nílò láti mú àmójútó lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ ní àsìkò yìí lọ́kùnkúndùn. Ó gbà á nímọ̀ràn pé, kí ẹ̀ṣọ́ oníṣẹ́ ọkọ̀ lójú pópó ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn LASTMA gba àwọn òṣìṣẹ́ síi.
Ilé Aṣòfin náà wá fẹnu kò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òlókoòwò àgbàyé ní àsìkò yìí, kí ìjọba sí sapá láti túbọ̀ ṣàmúlò àǹfààní ayẹyẹ ‘Detty December’ yìí.
Lánre Lágada-Àbáyọ̀mí