Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Kí Winifred Awosika Kú Ọjọ́ìbí

Lekan Orenuga

198

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti gbóríyìn fún Dókítà (Ìyáàfin) Winifred Awosika fún ìfara-ẹni-ṣápẹẹrẹ rẹ̀ sí ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, ní àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò àti olùrànlọwọ.

‎ Nínú ọrọ kán látí ọdọ Olùdámọ̀ràn pàtàkì Ààrẹ lórí Àlàyé àti Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga, Ààrẹ ṣàfihàn ìfaramọ́ Dókítà Awosika látí àwọn ọdọ ní àgbàrá fún ọjọ́ iwájú, Ààrẹ tún ṣé àkíyèsí pé àwọn ìgbìyànjú rẹ̀ farahàn lórí ètò ẹ̀kọ́ púpọ ní orílẹ̀-èdè yìí.

‎ Bó ṣé ń ṣé ayẹyẹ ọjọ́ìbí ọdún márún-dín-làádọ́run (85) rẹ̀, Ààrẹ Tinubu darapọ̀ mọ́ Ẹbí, ọrẹ àti ojúlùmọ̀ lórí ipá ìdàgbàsókè ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti ìfara-ẹni-ṣápẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tó ní ìrètí lórílẹ̀-èdè.

Comments are closed.

button