Àjọ UNICEF Pàrọwà Sí Àwọn Adarí Ìpínlẹ̀ Kano Láti Mú Ìgbòòrò Bá Àjẹsára Àwọn Ọmọdé
Àjọ UNICEF ti pàrọwà sí àwọn ọba alayé àti alákòsóo ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo láti mú ìgbòòrò bá abẹ́rẹ́ àjẹsára àwọn ọmọdé èyí tí yóò dènà àrùn ní papàá jùlọ àrùn rọpá-rọsẹ̀
Priyanka Khanana tí ó jẹ́ agbẹnusọ àjọ UNICEF ni ó pe ìpè náà ní ìlú Kano níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó wáyé fún àwọn alákòsóo ìjọba ìbílẹ mẹ́rìnlélógójì tí ó wà ní ìpínlẹ̀ náà àti àwọn adarí lójúnà àti gbógunti àrùn rọpá-rọsẹ̀
Ó sàfirinlẹ̀ pé gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára lóòrè-kóòrè se pàtàkì láti dènà àrùn, ó wá késí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti se ìrànlọ́wọ́ lójúnà ati tán ìsòro náà