Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ikọ̀ Eyimba FC, Stanley Eguma, ti sọ pé rírẹ̀ tó rẹ ikọ̀ òun ló jẹ́ kí wọ́n ta ọ̀mìn pẹ̀lú ikọ̀ Heartlands FC nínú ìdíje ti ọjọ́ ọ̀kànlélógún ti Nigeria Premier Football League (NPFL).

Bóòlù ti wọ́n gbá ni pápá-ìseré Enyimba ni ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ jẹ́ kí Daniel Ekpo gbá bọ́ọ̀lù wọlé fún alátakò ni iṣẹ́jú méjìdínlógún pẹ̀lú ayò golí wò kí n gba síọ, ki
Joseph Atule ti ikọ̀ Enyimba tó wá dáa padà ní ìsẹ́jú márùndínlọ́gọ̀ta.

Ọgbẹ́ni Eguma sọ fún àwọn oníròyìn níbi ti wọ́n ti n fi ọ̀rọ̀ wa lẹnu wò pé ikọ̀ òun ni àfojúsùn láti borí ṣugbọn wọ́n tà ọ̀mìn ti o jẹ́ ki wọ́n ni àmìn ẹyọkan soso.
” A gbá bọ́ọ̀lù dáradára, ọlá pé wọ́n ń gbá ìdíje méjì lọ́sẹ̀ kan, ti kọ́tínẹ́ntì àti ti
NPFL nítorí èyi ló jẹ kí ó rẹ̀ wọ́n “.

Àbájáde bọ́ọ̀lù ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ ti NPFL nìyí:
Enyimba, oókan sí oókan (1-1) Heartland
Katsina United(oókan sí oódo (1-0)Plateau United
Niger Tornadoes , eéjì sí oókan 2-1) Kwara United
Rivers United, eéjì sí eéjì (2-2) Bendel Insurance.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san