Orílẹ̀-èdè Uganda ti sọ àwídájú pé òtíttọ ni pé àrùn Ebólà ti sú yọ bi òsùmàrè ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, Kampala pẹ̀lú ẹni àkọ́kọ́ tó lùgbàdí rẹ̀ bó se ń kú lọ ní ọjọ́ Ọjọ́rú, Mínísírì ètò ìlera sọ èyí ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀.
Ìgbà kẹsàn án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nìyí ti ilẹ̀ ìlà oòrùn Adúláwọ̀ yí yóò ṣe alábàpàdé rẹ̀ tí ó sì kọ́kọ́ ríi ni ọdún 2000.
Alaisan náà, Nọ́ọ̀sì Ọkùnrin ni ilé ìwòsàn
Mulago National Referral ni Kampala ti kọ́kọ́ wa itọju káàkiri ni Mulago àti ọ̀dọ̀ àwọn oníwòsàn ìbílẹ̀ nígbà tí ó kòfìrí nǹkan bí ibà.
” Alaisan náà ni ìdákúrekú àìsàn orísìí ẹ̀yà ara to se pàtàkì to sí n gba ìtọ́jú ni ilẹ ìwòsan Mulago National Referral ni ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kínní. Àbájáde àyẹ̀wò fi hàn pé ó ti ni àrùn Sudan Ebola Virus ipa,” Mínísírì sọ eyi nínú àkọsílẹ wọn.
Mẹ́rìlélógójì ènìyàn ni ẹni náà tó ti kú báyìí ti fara kàn ni wọ́n ń wá fún àyẹ̀wò ti òṣìṣẹ́ ìlera sì jẹ́ ọgbọ̀n nínú wọn, bi Mínísírì se sọ.
Àjọ World Health Organization ti ya mílíọ̀nù kan dọ́là sọ́tọ̀ fún ìrànwọ́ kí àrùn náà tó tan kálé káko.
Ilẹ̀ Uganda ni írírí àrùn yíì gbẹ̀yìn ni ìgbẹ̀yìn ọdún 2022 to sí pa marun din lọ́gọ̀ta ènìyàn nínú mẹ́tàlélógòje ènìyàn tó fọwọ́ bà. Àjàkálẹ̀ àrùn náà ni wọ́n kéde ni ọjọ kọkànlá osu kínní ọdún 2023.
Abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà àrùn Ebola fún gbogbo àwọn ti ẹni náà ti fara kàn yóò bèrè lọ́gán, Mínísírì sọ eyi.
Àjàkálẹ̀ àrùn Marburg – ìbátan Ebola náà bẹ sílẹ ni orilẹ-ede ti múlẹ ti wọn,Tanzania ni ọsẹ to kọjá. Ilẹ̀ Uganda
pààlà pẹ̀lú Rwanda níbi ti Àjàkálẹ̀ àrùn Marburg ti su yọ àti ilẹ̀ Kóngò níbi ti àrùn Ebola wọ́pọ̀ sí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san