Aya Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Sénétọ̀ Oluremi Tinubu ti gbé Mílíọ̀nù
Àádọ́talélọ̀dúnrún Náírà kalẹ̀ fún Ìpèsè eré orí ìtàgé láti bu ẹwà kún àṣà àti ìṣe ìpínlẹ̀ Kwara látàrí irin isẹ́ àwòmáleèlọ tó bá ìgbà mu ti Kwara State’s Sugar Factory Film Studio gbé kalẹ̀ àti bi àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà se kíi káàbọ̀.
Aya ààrẹ se àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́ta sí ìpínlẹ̀ Kwara ni ọjọ Ìṣẹ́gun níbi tó ti sí ọ̀pọ̀ àkànṣe iṣẹ́ tí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ti se bíi Bírìjì olókè Méjì ti wọ́n fi bọlá lórúkọ Emir ti Ilọrin, Dókítà Ibrahim Kolapo Sulu-Gambari àti olóògbé Ọ̀gágun Tunde Idiagbon.
Sénétọ̀ Tinubu tún sí Innovation Hub, Ilé Isẹ́ aṣọ – Garment Factory ati Sugar Factory Film Studio, níbi tó ti gbé owó sílẹ̀.
Igbákejì àgbá pàtàkì ọ̀rọ̀ ìròyìn tuntun sí Gómìnà ìpínlẹ̀ kwara, Olayinka Fafoluyi sọ pé, Sénétọ̀ Oluremi gbìyànjú gan ni fún ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san