Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ wí pé àwọn ṣetán láti ṣe iranlọwọ fún dídènà àìsàn to wáyé nipa ẹfọn NTD èyí tí o n ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Dọ́kítà Iziaq Salako tó jẹ Mínísítà fún ètò ìlera àti ìtọ́jú àwọn ènìyàn ló sọ èyí di mímọ̀ ni ìlú Abuja lásìkò tí o n ṣe ìdánilékòó nípa àìsàn NTD.
Salako ni o jẹ ọjọ pàtàkì àti anfààní nlá láti ṣe ìdánilékòó lori àìsàn NTD náà
Ó ní pàápàá jùlọ láti jẹ kí àwọn ènìyàn mọ ona abayọ sí àìsàn náà àti kí àwọn tọrọ kàn le da sí pẹlu ki wọn sí mó ona láti dènà àìsàn náà