Take a fresh look at your lifestyle.

Ìlàkààkà Ààrẹ Tinubu Láti Mú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Dé Ilẹ̀ Ìlérí Ń So Èso Rere- Àwọn Alẹ́nulọ́rọ̀

140

Mínísítà Fún Ohun Àlùmọ́ọ́nì, Ọ̀gbẹ́ni Dele Alake àti Gomina Ìpínlẹ̀ Kaduna Uba Sani ti sàpèjúwe ìgbésẹ̀ ìsèjọba Ààrẹ Bọla Tinubu gẹ́gẹ́ bí èyí tí yóò mú ìyípadà ọ̀tun bá Orílẹ̀-èdè, tí yóò sì sọ ayé di gbẹdẹmukẹ fún mùtú-mùwà

 

Wọ́n sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́kan tí ó wáyé, wọ́n sàfihàn àfojúsùn wọn sí ìgbésẹ̀ ìjọba àpapọ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́, tí yóò sì mú ìdàgbàsókè bá Orílẹ̀-èdè lápapọ̀

 

Gómìnà Sani sàfirinlẹ̀ pé, àtúntò ìjọba àpapọ̀ wáyé pẹ̀lú ìnira àti ìpèníjà, sùgbọ́n lẹ́yìn ìnira, ìdẹ̀kùn lókàn, àtipé láìpẹ́ tolórí-tẹlẹ́mù ni yóò gbádùn tí ayé yóò sì di gbẹdẹmukẹ fún mùtú-mùwà

 

 

Comments are closed.

button