Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Ebonyi: Ẹgbẹ́ Labour Party Tí Rọ Gómìnà Nwifuru Láti Ṣe Iṣé Ọ̀gbìn.0

155

Akòwé fún ẹgbẹ́ LP Amòfin Luke Chibueze Adonwe tí rọ Gómìnà Francis Nwifuru láti ṣe iṣé àgbẹ̀ fún Ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Adonwe sọ èyí di mímọ̀ ni ìlú Abakaliki, sọ wí pé pẹ̀lú ohun gbogbo ti àwọn ènìyàn n la koja báyìí nì Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà iṣé ọ̀gbìn nìkan ló lé sọ di ìrọ̀rùn fún àwọn ènìyàn.

Ó ṣe àpèjúwe ìpínlẹ̀ Ebonyi gégé bíi ìpínlẹ̀ tó ṣe orire, ṣùgbọ́n ó kù fún ìjọba láti ṣe Ìrànlọ́wọ́ fún wọn ní agbègbè ètò ọ̀gbìn.

Ó rọ àwọn ìjọba láti ṣe Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn agbègbè kakakiri, pàápàá jùlọ àwọn òpópó-ònà, láti leè jẹ ko rọrùn fún ètò káràkátà.

Comments are closed.

button