Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Saudi Arabia Dá Ọmọ Nàìjíríà Mẹ́ta Sílẹ̀ Látàrí Ẹ̀sùn Oògùn Egbogi

187

 

Àjọ ọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ òkèèrè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kede idasile àwọn obìnrin mẹta ọmọ orílẹ̀-èdè yii, Hadiza Abba, Fatima Umate Malah, ati Fatima Kannai Gamboi ti wón ti wa látìmọ́lé lati bi oṣù mẹ́wàá látàrí ẹsun oogun egbogi ni Ilẹ Saudi Arabia.

Ìdásílẹ̀ wọn wáyé lẹyìn ọ̀pọ̀lopọ̀ ìlànà ti ofin olojo gbọọrọ léyìn ti wón ti mú wọn ni ọjọ karùn ún osu kẹta odún 2024 ni pápákọ̀ òfurufú ti Prince Mohammad bin Abdulaziz ni Madinah.

Àkọsílẹ lati Minisiri ti olùdelé agbenusọ,
Kimiebi Imomotimi Ebienfa fi sita wipe àwọn obìnrin náà wọn kò fi gbogbo ara lọ́wọ́ ninu ẹ̀sùn ti wón fi kàn wọ́n sugbọn ẹ̀sùn àtijọ́ wọn ló jẹ ki wọ́n mú wọn.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àjosoyépò, Mínísírì náà jẹ́ kó yé wa pé wọn ti da awọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sílẹ̀ ni àlàáfíà ti wón sì ti fi wọn lé eka ọ́fíìsì ti Nàìjíríà ní Jeddah lọwọ láti lọ darapọ̀ mọ àwọn ẹbí wọn.

 

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbíisẹ̀san

 

Comments are closed.

button