Bísọ́ọ̀bù Àgbà ti ìjọ Kátólìkì, ẹni ọ̀wọ̀ Dókítà Ignatius Kaigama ti ní ìrètí àti ọjọ́ ọ̀la tó dára fún odún 2025, Ó wá pè àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wá ni ìfé, isọ̀kan àsọyépọ̀ ẹlẹsin jẹ̀sìn to dára ni orílẹ̀-èdè yìí
Bísọ́ọ̀bù Àgbà, Kaigama sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro ni orílẹ̀-èdè yii ń dojúkọ lóòtọ́ sugbon ọjọ́ ọ̀la wa nbọ̀ wá dára.
Lẹyìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ yóò tan ki a máà sọ ìrètí nu ki a sí máa ṣe rere, ” ó fi kun.
Ó sọ síwájú pé kì a pada sí ẹsẹ ẹ̀sìn òtítọ ti o jẹ eléyìí tí o lee so wá pọ̀ dain-dain.
“Ẹ̀sìn wá láti inu ọrọ Látìnì to túmọ sí “díi papọ̀”. O nilati di eniyan papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, eyi jẹ ìtumọ̀ ohun ti esin leè se.
.
” Sugbon a ti sọ ẹṣín di òṣèlú. A ti sọ ẹṣìn di ohun ìjà olóró, èyí ló fà ti ẹ̀sìn se sọsẹ́ fún wa”, o sọ èyí.
“Bi. o jẹ ẹsin Buddhism, Hinduism, ìgbàgbọ tabi Ìmọ̀le ko sí eni to sọ fún ọ pe ki o pànìyàn, ko si ẹni to so fún ọ pe ko foju tẹ́mbẹ́lú ẹnìkejì. Ti o ba fẹ jèrè ẹnikan fún èsìn rè, jẹ ki ìmọ́lẹ̀ rẹ tàn ko sí sọ̀rọ̀ fún ọ, ẹ jẹ ki ààyè lati se ẹṣin tó wùwá wà.
” Ó túmọ̀ sí pé ọmọbìnrin Mùsùlùmí leè fe ọmọkùnrin Ìgbàgbọ, ọmọkùnrin Ìgbàgbọ, ai lee fe ọmọbìnrin Mùsùlùmí pẹ̀lú àlàáfíà àti ìdùnnú. A kò sí gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ wa dùnwá. A níláti máa gbé ni ìrẹ́pọ̀ ni ti ẹsin tó ti wọ inú ara wọn, ” o pari pèlú èyí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san