Ẹ Fọkàn Balẹ̀ : Kòsí Àrùn Ìgbàlódé Covid-19 Variant Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà: Ìjoba Àpapọ̀ Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Àrídájú
Ẹka Ìjọba Àpapọ̀ tí ó ń rí sí ètò ìlera ti fi ọmọ Orílẹ̀-èdè Naijiria lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀lú àrídájú wípé àrùn Covid-19 tí ó wà ní apákan àwọn Orílẹ̀-èdè àgbáyé kò sí ní Orílẹ̀-èdè Naijiria. Ìjọba pè fún ìmọ́tótó àti ìtẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìjọba lórí ètò ìlera
Nínú ọ̀rọ̀ kan tí Alaba Balogun tí ó jẹ́ igbákejì alákòsóo ìfọ̀rọ̀léde àjọ náà sọ, ó sàpèjúwe ọ̀rọ̀ tí ó ń jà káàkiri wípé àrùn náà wà ní Orílẹ̀-èdè Naijiria gẹ́gẹ́ bíi aásà tih kò ní kán-ún, ọ̀rọ̀ òfegé, èyí tí kò fìdí múlẹ̀
Àlàyé náà wáyé látàrí ìwé àtẹ̀jíṣẹ́ kan tí ó jáde ní ọjọ́ karùn-ún osù kejìlá ọdún 2024 èyí tí ó ti dá wàhálà sílẹ̀ láàrin àwùjọ nípa wípé kí olórí di orí rẹ̀ mú, idà ń jò bèlè-bèlè
Ìròyìn fi yéwa pé àrùn náà ti wà ní Orílẹ̀-èdè Australia, èyí tí ó sì ti tàn ká dé Orílẹ̀-èdè àgbáyé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n míràn. Látàrí ìdí èyí, ìjọba àpapọ̀ ti n gbaradi ni gbogbo ọna lati dènà àrùn náà.