Ikọ̀ Flying Eagles ti Nàìjíríà ti ọjọ orí wọn kò kọjá ogún ọdún ti wọ Ipele tó kángun sí àsekágbá ti ọdún 2024 West African Football Union (WAFU) B U20 lẹ́yìn ti wọ́n lù ikọ̀ Cote D’Ivoire ni ayò méjì sí oókan ( 2-1 ) ni ayo akọkọ wọn tó kù.
Ìkọ ti Nàìjíríà ti kọ̀kọ́ fìdí rẹmi pelu ayò kan si odo (0-1)sọwọ Burkina Faso ni ayo ibẹrẹ isori B, ìkọ Burkina Faso náà pàdánù sọ́wọ́ Cote D’Ivoire pẹlú ayo kan si odo(0-1).
Ìkọ Naijiria to jẹ Olubori idije ti odun 2022 WAFU B ló ń léwájú ni ìsọ̀rí wọn nítorí ore ọfẹ ayo méjì ti won ni, ikọ̀ Ivory Coast lo se ipo keji pẹlú góòlù méjì, ikọ̀ Burkina Faso ti já kúrò níbi idije náà pèlú ipò kẹta.
Ìkọ Naijiria to nlewaju ni isori B yóò fẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlú ìkọ Niger Republic to ni ayò mẹrin ní ìsòrí A.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san