Take a fresh look at your lifestyle.

Ààre Tinubu Sèdárò Alága Ìdìbò Tẹ́lẹ̀rí Humphrey Nwosu Tó Papò Dà

147

 

Ààre Bola Ahmed Tinubu ti kedun gidigidi latari iku, Kofesọ̀ Humphrey Nwosu. O jẹ Alaga Idibo, National Electoral Commission (NEC), teleri, o ku ni ile iwosan orilẹ-ede Amerika.

Ààre Tinubu kedun pẹlú ebi ati ọrẹ ẹni ire to lo, o sọ pé, ojogbon Nwosu sa ipa rere fún ijoba awarawa ti a n gbadun bayi. Ààre ko gbagbe ibo ti àjọ – NEC dari, ti gomina, ààrẹ ati ti ile igbimọ aṣòfin. Eto, OPTION A-4, ti oludibo yóò to seyin foto tabi aworan Oludije ni awon Ibudo idibo gbogbo.

Wọ́n bi ọjọgbọn Humphrey Nwosu ni ọjọ keji oṣu kewaa Odun 1941 ni ìpínlẹ̀ Anambra.

Ó jẹ ààrẹ eleto idibo ajo NEC Naijiria lati odún 1989 titi di 1993 . O darí eto idibo ààrẹ malegbagbe ọjọ Kejìlá osu kẹfà odun,1993 ti ọgagun Ibrahim Babangida fagile.

Ààrẹ Tinubu gbàdúrà pé kí Ọlọrun dẹlẹ̀ fún ẹni ire to lọ, ko fiku se isinmi fún, kó sì tu àwọn to fi sílẹ̀ lọ nínú.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button