Àjọ tó ń mójú ìdàgbàsókè agbègbè ní ìjọba ìpínlẹ̀ Edo ti ṣe Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn oníṣẹ́ ọ̀gbìn tó jẹ Obìnrin ni ìjọba ìbílẹ̀ Uhumwode nipa Pin Pin àwọn ohun tí yóò mú Ìdàgbàsókè ba àwọn èrè oko wọn.
Awọn ǹkan ọ̀gbìn bi, àmúewébẹ̀ dàgbà,ogún tó n pa kòkòrò àti bẹẹ bẹẹ lọ
Iyaafin Christabel Ekwu tó jẹ́ kọmísọ́nà fun ìdàgbàsókè àwọn ará ìlú gbóríyìn fún àwọn Obìnrin ni Ọjọ́bọ̀ lori akitiyan wọn láti rí wí pé ètò ọ̀gbìn n dàgbà sókè ni ìpínlẹ̀ náà.
Ekwu ni ohun ti ìjọba ṣe yìí wa lára ìlérí rẹ láti rí wí pé ìdàgbàsókè bá ètò ọ̀gbìn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní ìpínlẹ̀ náà.
Kọmísọ́nà fún ètò ọgbin ati oúnjẹ ọ̀gbẹni Stephen Idehenra tẹnumọ pàtàkì tó wà nínú ki ijoba ṣe atilẹyin fún àwọn obìnrin nipa, ètò Ẹ̀kọ́, ọ̀gbìn,ikose ati Ìdàgbàsókè ìlú.
Ó ní nise lo n má mu ìdàgbàsókè bá ìlú, agbègbè, ìbílẹ̀, ipinlẹ, Orílẹ̀-èdè àti àgbáyé lápapò.