Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje Tennis: Rafael Nadal Bẹ̀rẹ̀ Jíjáwé Olùborí Ni Ilu Barcelona

85

 

Ìràwọ̀ agbábọ́ọ̀lù Tennis, ọmọ orílẹ̀-èdè Spain, Rafael Nadal ti pada sinu ìdíje ni oṣù kínní odun ni Brisbane láti nǹkan bí ọdún kan latari ifarapa ibi ìdí to nilo iṣẹ abẹ. Ẹ̀wẹ̀, ifarapa ti fẹ hee leemọ̀, Ifarapa iṣan ese yiya lo fa ti ko fi leè kópa fún Australian Open àti ọpọlọpọ ìdíje ni Doha, Indian Wells àti Monte Carlo.

Ó lu alatako rẹ, Flavio Cobolli ọmọ ilẹ Italy ni ayò mẹfa sí méjì, mẹfa sí meta(6-2 6-3) ni ilu Barcelona ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun. Eyi jẹ ayo rẹ àkókò leyin to ti borí ni ti ọdún 2022 French Open.

Nadal ni afojusun ati wa ni ipò àlàáfíà nínú ìdíje French Open àti lati gbadé ìdíje náà ni ìgbà kàrúndínlógún.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Comments are closed.