Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Bú Ọwọ́ Lu Ìfilọ́lẹ̀ Àjọ Agbófinró Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

98

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti bú ọwọ́ lù Àbádòfin ìfilọ́lẹ̀ Àjọ Agbófinró Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo State Rule of Law Enforcement Authority) ti yóò máa sàmójútó pípa ìlànà àti òfin mọ́.

Makinde, ẹni tó fi ọwọ́ sí Àbádòfin náà nígbà tó yan Onídàájọ́-fẹ̀yìntì Aderonke Aderemi gẹ́gẹ́ bíi Alága Àjọ náà ló rọ gbogbo olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti máa bọ̀wọ̀ fún òfin ki Ìpínlẹ̀ náà lè gòkè àgbà.

Ètò yii ló waye ni Ofiisi Gómìnà to wà ní Sekiteriati ìjọba ni agbègbè Agodi ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, nibi tí igbákejì Gómìnà, Bayo Lawal, Akowe Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olanike Adéyemí, Olori Òṣìṣẹ́, Olubunmi Oni àti igbákejì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Mohammed Abiodun Fadeyi ti péjú.

Gómìnà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ kó di mímọ̀ pé òun ṣe àgbékálẹ̀ Àjọ yìí lójúnà àti dí àlàfo tó wà láàárín ifidi múlẹ̀ òfin tó n sàmójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀, ìmọ́tótó àyíká àti àwọn nkan míràn látàrí onírúurú ìpèníjà eléyìí tó n wáyé nítorí àìsí iṣọkan láàrin àwọn òfin Ìpínlẹ̀ àti tí Ìjọba Àpapọ̀.

Gómìnà fi àsìkò náà tẹnu mọ ìdí pàtàkì ti óun fi gbe àbá náà lọ iwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní láti rí dájú pé ìdájọ́ tó yẹ wà fún gbogbo ẹni yìówù tó bá tako òfin nítorí àwọn àkọsílẹ̀ oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ tó là ikú lọ eléyìí tó ti wáyé látàrí ṣíṣe lòdì sí òfin tó dènà ìgbòkègbodò ọkọ̀, títà ọjà lójú pópó àti dídá idọti sí àárín òpópónà.

O wá fi àsìkò náà mu da Àjọ náà lójú pé ìjọba yóò kún wọn lọ́wọ́, nígbà tó ṣàlàyé pé ọ̀nà kan gbógì ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi lè gòkè àgbà ni ki àwọn èniyàn rẹ̀ fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba.

O tun fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìjọba yóò pèsè àwọn yàrá ìdájọ́ alágbèéká káàkiri, nígbà tó tẹnu mọ́ pé gbogbo ẹni yìówù tó bá tápà sí òfin ni yóò gba ìdájọ́ ni kíákíá laifi ìgbà tàbí àkókò ṣe.

Gómìnà tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjọba kò ní duro lori fífi ofin múlẹ nikan sugbon yóò tún gbìyànjú láti máa lá àwọn ènìyàn lóyè láti máa ṣe ohun tó bá òfin mu.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.