Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde San Bílíọ̀nù Méji Náírà Fún Àwọn Alága Ìjọba Ìbílẹ̀

69

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kéde pé ìjọba ti san Bílíọ̀nù méjì Náírà lára ẹ̀tọ́ àwọn Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ tó wà níbẹ̀ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Makinde lo sọ di mímọ̀ pé, ìgbésẹ̀ sísan lára ẹ̀tọ́ àwọn Alága náà yóò mú ki òpin dé bá ìjà ọlọ́jọ́ pipẹ to wa láàrín ẹgbẹ́ ALGON àti òun lẹyìn tó júwe ilé fún wọn ní ọdún 2019.

Makinde lo sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìsìnkú fún ẹni tíì ṣe mama Mínísítà tẹlẹrí fún Eré Ìdárayá àti ọ̀rọ̀ Ọdọ, Màmá Ruth Adenihun Dare. Ìsìn idupẹ to waye ni ile ìjósìn Baptist ni agbègbè Sabo ni ìlú Ogbomoso ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Makinde tẹnu mọ́ pé ìdí pàtàkì ti òun fi wa lati darapọ mọ mínísítà náà láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún màmá rẹ̀ tó di olóògbé ni ẹni ọdún Mejilelaadorun (92) ṣe àfihàn wí pé ọkan ní gbogbo olóṣèlú. O wá gbàdúrà kí Ọlọrun tẹ màmá sí afẹ́fẹ́ rere, kò sí tọjú gbogbo àwọn ti màmá fi sàyè.

Makinde fi àsìkò náà mu wá sí ìrántí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pe, ìṣèjọba òun ti fún àwọn Alága náà ni Bilionu kan Náírà (N1b) ní ọdún 2021, ni ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ ti ilé ẹjọ́ tó ga jù dá wí pé kí òun sàn ẹ̀tọ́ àwọn Alága náà fún wọn.
O wá fi àsìkò náà tẹ mọ gbogbo ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ létí láti yàgò fún ohun tó lè fa dàrú-dàpọ̀ láàrin wọn nítorí òṣèlú, nígbà tó fi kún pé gbogbo olóṣèlú lo mọ ọ̀nà tí wọn máa fí n ba ara wọn làjà.

O wá sọ di mímọ̀ níbi ìsìn náà pé òun tún n padà bọ̀ wá sí ìlú Ogbomoso láìpẹ́ láti wá ṣí òpópónà òní kilomita méjìdínlogorin àti diẹ (78.6km) ti Ogbomoso-Iseyin-Fapote eléyìí tí wọn fi sọ orúkọ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹlẹrí, Adebayo Alao-Akala.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.