Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Bá Odidiọmọ Kẹ́dùn Ikú Bàbá Rẹ̀

103

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òyó, Seyi Makinde ti ba ọ̀kan lára ọmọ ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin, tó ṣoju Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Ìbàdàn/Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn Ìbàdàn, Stanley Olajide lórí ikú bàbá rẹ̀, Abdullateef Akin-Tokunbo Olajide.

Makinde, ẹni tó bá Olajide,ti wọn mọ sí Odidiọmọ kẹ́dùn ikú bàbá rẹ̀ náà ló gbàdúrà kí Ọlọrun tẹ́ olóògbé náà sì afẹ́fẹ́ rere, nígbà tó gbàdúrà kí Ọlọrun fún àwọn mọ̀lẹ́bí ni okun láti gba ìṣẹ̀lẹ̀ náà mọ́ra.

Alhaji Olajide tó jẹ́ bàbá Odidiọmọ ló di olóògbé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì (12/04/2024), ti Gómìnà sí sọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun bá a kẹ́dùn bàbá rẹ̀ tó re ibí àgbà n rè. O wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ pé ikú àwọn tó jẹ́ olólùfẹ́ ẹni máa n dunni jọjọ, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́ran ara, ènìyàn ní láti gba fún Ọlọrun ni.

O wá gbàdúrà ki Ọlọrun gba ni àbọ̀ olóògbé náà.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.