Take a fresh look at your lifestyle.

Ipò Olúbàdàn: Ìgbìmọ̀ Olúbàdàn Fa Ọ̀tún Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn Kalẹ̀

109

Àwọn ìgbìmọ̀ Olúbàdàn ti fi orúkọ Ọ̀tún Balogun Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Owólabí Akinloyè Ọlakulẹhin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn tó kàn

Ọba Ọlakulẹhin ni àwọn ìgbìmọ̀ Olúbàdàn kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn Kẹtalelogojì (43) nínú ìpàdé tí àwọn Afọbajẹ ṣe ni Ààfin Olúbàdàn tó wà ní agbègbè Ọjà’ba ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Òyó ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Ọba Ọlakulẹhin ni Òsì Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Lateef Adebimpe fa kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ipò náà kàn labẹ òfin nínú ìpàdé to wáyé ni Ààfin Olúbàdàn, níbi ti Ọ̀tún Olúbàdàn, ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ, Olóyè Rashidi Ladoja ti jẹ Alága.

Nígbà to n ba àwọn oníròyìn sọrọ lẹ́yìn ìpàdé náà, Olóyè Rashidi Ladoja fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ìgbìmọ̀ Olúbàdàn ló fa Ọba Ọlakulẹhin kalẹ̀ láti fi orúkọ rẹ̀ ṣọwọ́ sí Gómìnà Seyi Makinde.

Olóyè Ladoja wá tẹnu mọ́ pé àwọn ìgbìmọ̀ náà yóò jábọ̀ ìpàde náà fún Gómìnà, ẹni tí yóò fọwọ́ sí i ìyànsípò Ọba Ọlakulẹhin gẹ́gẹ́ bi Olúbàdàn to kàn.

Nígbà tí Ọ̀tún Balógun Ilẹ Ìbàdàn, Ọba Tajudeen Ajíbólá kó sí i níbi ìpàdé náà, ìgbimọ Olúbàdàn mẹsan tó kù tó péjú síbi ìpàdé náà ní: Ọ̀tún Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Oloye Rashidi Ladoja; Òsì Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Eddy Oyewole; Ashipa Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Oba Abiodun Koka-Daisi; Ẹkẹrin Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Hamidu Ajibade; Ẹkarun Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Adebayo Akande; Òsì Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Lateef Adebimpe; Ashipa Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Kola Adegbola; Ẹkẹrin Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Dada Isioye; ati Ẹkarun Balógun Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Abiodun Azeez.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.