Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Fi Ẹ̀bùn Ọkọ̀ Méjìdínlọ́gbọ̀n (28) Fún Àwon Ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga.

141

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí wí pé, bo tilẹ̀ jẹ́ pé ohun gbogbo gbé owó lórí, ìṣèjọba òun yóò tẹ̀ síwájú láti máa ṣe ohun tí yóò mú kí ará tu àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gómìnà lo sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n fi ọkọ̀ elérò méjìdínlógún (18 seater) Méjìdínlọ́gbọ̀n (28) fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ètò fífi ọkọ̀ fun àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga náà ló wáyé ni ibùdó ìgbọ́kọ̀ sí tó wà ní Sekiteriati ìjọba tó wà ni agbègbè Agodi ni ìlú Ìbàdàn

Makinde, ẹni tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni àwọn ọmọ Orilẹ èdè Nàìjíríà n dojú kọ ìpèníjà alágbára, ṣùgbọ́n o fi àsìkò náà dà wọn lójú pé ohun gbogbo n bọ̀ wá dẹ̀rọ̀ láìpẹ́, nígbà tó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú láti ní àforítì nítorí ohun gbogbo to le yóò di ohun ìgbàgbé láìpẹ́ ọjọ́.

Bákan náà, Makinde ni oun ti bú ọwọ lù sisan owó (bursary award), ti ọdún 2024 fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó sì ṣèlérí pé òun yóò rí dájú pé owó náà jẹ́ sísan láì fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú. O wá rọ wọn láti fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ wọn.

Bákan náà ni Gómìnà tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun yóò tún ṣe àgbédìde sísan owó (bursary) fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga láti àpò ara rẹ̀, nígbà tó tẹnu mọ pé, òun ti n ṣe nkan yii tẹlẹrí ṣùgbọ́n tí òun da ọwọ́ rẹ̀ dúró nígbà tí òun di Gómìnà. O wá fi dá wọn lójú pé òun yóò tún bẹrẹ síi ṣe eyi nítorí ìjọba nìkan kò lè ṣe iṣẹ́ ìlú.

Makinde wá sọ di mímọ̀ pé owó ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lórúkọ Seyi Makinde, (Seyi Makinde Scholarship Scheme) yóò fìdí múlẹ̀ nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí àsìkò yìí, nígbà tí oun yóò bẹ̀rẹ̀ sísan owó náà ni nkan bíi ọ̀sẹ̀ mẹjọ sí àsìkò yìí.

Ṣáájú èyí ni Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ pataki fún Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́, Victor Olojede ti fi àsìkò náà lù Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún ìgbìyànjú rẹ ati akitiyan rẹ, ni pataki jùlọ bo ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ẹ̀bùn ọkọ̀.

Bákan náà ni ọkan lára àwọn adari àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fi Gómìnà Makinde we ọ̀rẹ́ ará ìlú.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button