Ìjọba orílẹ̀-èdè Senegal ti kéde pé idibo sí ipò ààrẹ yóò wáyé ni ọjọ kẹrìnlélógún oṣù keta.
Ikede yi ri bẹẹ latari awuyewuye isunsiwaju ti ààrẹ Macky Sall ti kọkọ se losu to koja, to fa iwode to tan kaaakiri bí ina igba ẹ̀rùn
Ààrẹ ti sáà rẹ yoo kogba wọlé ni ọjọ keji oṣù kẹrin náà ti sọ pe oun ko lero làti kopa ninu ibo ààrẹ ní ìgbà ẹ̀kẹta. Àwọn alatako rẹ tilẹ̀ sọ pé ìdìtẹ̀egbàjọba olofin lọ fe se.
Senegal jẹ ọ̀kan lara Orile-ede ti ìjọba awarawa ti rawọ tilẹ ni ilẹ Adulawọ. Ológun ko gba ijọba ri ni Orílẹ̀-èdè náà.
Ààrẹ Sall ti lo sáà méjì, o si ti ṣèlérí ni ọdún 2012 nigba ti wọn dibo fún pé òun koni lo kọjá ìgbà ti oun da lọ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san