Ìgbákejì Ààrẹ Shettima Rọ́ Ìgbìmọ̀ Àmúṣẹ́yá Túntún Tí Àwọn Arìnrìn-àjò Sí Ilẹ̀-mímọ́ Látí Ṣ’íṣẹ́ Náà Dójú Àmì
Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima tí rọ́ àwọn ìgbìmọ̀ àmúṣẹ́yá túntún tí Ìgbìmọ̀ Arìnrìn-àjò àwọn Onígbàgbọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Nigerian Christian Pilgrim Commission NCPC) látí ṣ’iṣẹ́ náà dójú àmì.


Nígbà tó n bá àwọn aṣojú NCPC náà sọ̀rọ̀ tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ìgbákejì Ààrẹ rán àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ náà létí pàtàkì iṣẹ́ ẹsìn látí kojú àwọn ìpèníjà tó ń kojú lórílẹ̀-èdè yìí.


Ìgbákejì Ààrẹ tún jẹ́wọ́ ipá réré tí Ààrẹ Bola Tinubu lórí orílẹ̀-èdè náà, Ó fí àṣeyọrí tí Ààrẹ tí sí awọn ìbùkún Ọlọrun àtí ọkàn mímọ.