Take a fresh look at your lifestyle.

Ìfikùn-lukùn Yóò Wáyé Lójúnà Àti Pẹ̀tù Sí Awuye-wuye Tí Ó Sẹlẹ̀ Látàrí Fífi Òfin De Ọtí Inú Ọ̀rá- Ẹka Ìjọba Àpapọ̀

143

Ẹka Ìjọba Àpapọ̀ tí ó wà fún ètò ìlera ti gbáradì láti wá ojútùú sí ìfẹ̀hónúhàn tí ó wáyé láti ọwọ́ àjọ FOBTOB látàrí fífi òfin de ìpèsè, mímu àti títa ọtí inú ọ̀rá, èyí tí ó wáyé ní ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ àjọ náà ní ìlú Abuja

 

Nínú ìfiléde kan tí ó wáyé èyí tí adarí ìfọ̀rọ̀léde àjọ náà, Deworitshe Patricia fi ọwọ́ sí, ó sàlàyé pé mínísítà fún ètò ìlera, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ali Pate fi àrídájú hàn pé Òun yóò wòye sí  ìfẹ̀hónúhàn àjọ FOBTOB lójúnà àti wá ojútùú sí i

 

Alága àjọ FOBTOB, Ọ̀gbẹ́ni Jomoh Oyibo fi àìdùnnú ọkàn hàn látàrí ìgbésẹ̀ àjọ NAFDAC lórí fífi òfin de pípèsè, mímu àti títa ọtí inú ọ̀rá, sùgbọ́n ìrètí wà pé ìjọba yóò wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà láìpé jọjọ.

Comments are closed.

button