Alága àjọ AMAC, Ọ̀gbẹ́ni Christopher Zakka ti pàrọwà sí àwọn tí ó ń san owó-orí láti san owó sí akoto ìjọba èyí tí àjọ AMAC gbé kalẹ̀
Alága sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ láti jìnà sí àwọn kòlọ̀rọ̀sí ènìyàn kan tí ó ń gba owó orí lọ́na àlùmọ̀kọ́rọ́yí
Ọ̀gbẹ́ni Zakka sàlàyé pé, àjọ náà fi ń dá àwọn ènìyàn lójú pé, ìdẹ̀kùn yóò wáyé fún àwọn ènìyàn látàrí gbígba owó orí ní ọdún yìí nítorí ìlekoko ọrọ̀ ajé tí ó ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́ ní Orílẹ̀-èdè Naijiria.