Ókéré tán ẹ̀mí mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ènìyàn ti segbe ninu ija ẹlẹyamẹya ni ariwa òkè orílẹ̀-èdè Papua New Guinea ni ọjọ́ ajé.
Àwọn ọkunrin náà ni wọn pa ninu ibùba ni agbègbè Enga bí ìròyìn se sọ.
Rogbodiyan náà ṣẹlẹ ni ọjọ Aiku látàrí ija lààrin ẹ̀yà méjì.
Olopaia ti kọkọ sọ pé ènìyàn mẹ́tàléláàdọ̀ta ló kú, kí wọn tó ṣẹṣẹ wa da padà sí ènìyàn mẹ́ridínlọ́gbọ̀n
“Iroyin ti ko dun gbọ leti ni èyí to jade wa láti Papua New Guinea,” Olórí Australia, Anthony Albanese sọ èyí ni ọjọ́ ajé.
A máa se àtìlẹyìn, papa ju fún àwọn ọlọ́pàá àtí agbófinró ni Papua New Guinea”, ó fi kun.
.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san