Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Kéde Sisan Owó Òṣìṣẹ́ To Kéré jù Fún Oṣù Mẹ́fà Míràn

170

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kéde sisan Ẹgbẹ̀rún Márùndínlọ́gbọn (N25,000) fún òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ẹgbẹ̀rún Márùndínlógún Náírà (N15,000)fún òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì fun oṣù mẹ́fà síwájú síi.

Makinde ló kéde èyí lásìkò tó lọ ṣí òpópónà òní kilomita Méjìlá àti ààbọ̀ (12.5Km) láti Challenge/Odo-Ona Eléwé sí Àpáta ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Nígbà tó n sọrọ, Makinde ni ìtèsíwájú nínú sísan owó fún òṣìṣẹ́ to kéré jù náà ṣe pàtàkì kí Ìjọba Àpapọ̀ fí lè parí iduna-dura pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí iye tí owó oṣù òṣìṣẹ́ to kéré jù yóò jẹ́.

Gómìnà Makinde náà ló ti bẹ̀rẹ̀ sísan owó yìí fún òṣìṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti osù kẹwàá ọdún 2023 láti mú ìtura dé bá ará ìlú látàrí bi ìjọba àpapọ̀ ṣe yọ owó ìrànwọ́ orí epo bentiro eléyìí tó fa bí owó epo bentiro ṣe gbẹnu sókè tó sì ṣe okùnfà ọwọn gógó nkan.

Gómìnà ṣàlàyé pé òun gbé ìgbésẹ̀ yìí lati jẹ́ kí ará le tu àwọn òṣìṣẹ́ àti òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni u eyi tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé owó náà yóò jẹ sisan fún oṣù mẹ́fà.

O wá fi kún àlàyé rẹ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ yóò tẹ síwájú láti gba owó náà fún oṣù mẹ́fà síi lati lè faaye fún iduna dura láàrin Ìjọba Àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù.

Abiola OloweÌ

bàdàn

Comments are closed.

button