Onídàájọ́ Olusola Adetujoye, O.A. Lajide àti S.O. Adeyemi ti ilé ẹjọ́ gíga to jókòó ní ìlú Ìbàdàn ti sọ àwọn Mẹ́ẹ̀dógún sẹ́wọn látàrí bi wọn ṣe lọwọ nínú jibiti orí ẹ̀rọ ayélujára.
Àwọn Mẹ́ẹ̀dógún náà ni wọn jẹbi ẹ̀sùn ti Àjọ EFCC fi kàn wọn láàrin ọjọ́ Kejìlèlógún oṣù kínní àti ọjọ kàrún oṣù Kejì ọdún yìí.

Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde ti Àjọ EFCC fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn, ọkan nínú wọn, Adebola Sherrif o di èrò ẹwọn latari esun marun ọtọọtọ.
Àwọn mẹ́rìnlá yòókù ní: Adebayo Ifeoluwa Timilehin, Philip Daniel, Ifemadi Haruna Segun, Okeola Olajide James Bolanle, Akinjisola Ayodeji Francis, Giwa Usman Dolapo, Olorunsola Sodiq Babatunde, Fatolu Moses Opeyemi, Bashiru Sodiq Omobolaji, Omowaye Oluwatosin Olamilekan, Badmus Yusuf Omobolaji, Lateef Ramon Olamilekan, Idowu Michael Oluwasegun àti Okunola Samuel Olalekan.
Nígbà tí ilé ẹjọ́ ká ẹsùn ti Ajo EFCC fi kàn wọn, gbogbo wọn sọ pé wọn jẹbi ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tó ṣe àfihàn iṣẹ́ jibiti ori ẹrọ ayélujára, ti àwọn agbẹjọ́rò sì bẹ ilé ẹjọ́ láti ṣe ìdájọ́ wọn bó ti tọ àti bó ti yẹ.

Lẹyìn tí ilé ẹjọ́ ti gbo atótónu àwọn agbejoro, Onídàájọ́ fi Yusuf, Sodiq àti Olamilekan sí ẹwọn oṣù mẹ́fà láti lo ṣe iṣẹ àgbègbè, nígbà ti Timilehin, Daniel, Segun, Bolanle, Ramon, Oluwasegun, Sherrif àti Olalekan lọ sí ẹwọn láti lọ ṣe iṣẹ́ àgbègbè fún oṣù kan.
Opeyemi, Babatunde, Dolapo àti Francis lọ ẹwọn láti lọ ṣe iṣẹ́ agbègbè fún ọsẹ méjì.
Nígbà tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún Yusuf láti san Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Ọgọ́rùn-ún Náírà (N100,000.00) gẹgẹ bí owó ìtanràn, ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún Olamilekan láti san Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Igba Náírà (N200,000.00), ti wọn sì pàṣẹ fún Sodiq láti san Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Àádọ́san Naira (N170,000.00).

Bákan náà, ilé ẹjọ pàṣẹ fún gbogbo wọn láti ṣe àsanpadà gbogbo ohun ti wọn fi jibiti gbà, ki wọn sì jọ̀wọ́ gbogbo ohun ti àjọ EFCC ká mọ wọn lọwọ fún ìjọba Àpapọ̀.
Abiola Olowe
Ìbàdàn