Sénétọ̀ láti Àríwá orílẹ̀-èdè yii, Sénétọ̀ Sunday Latung láti Gusu Kaduna ti sọ pe ìṣàkóso rere ni o se pàtàkì nínú ètò ijoba àwarawa.
Ó sọ pé, ipinle Bayelsa àti gbogbo eniyan Ijaw nilo ìjoba rere bí eleyi ti gomina Douye Diri ti n se láti ìgbà to ti gori aleefa. Isakoso jẹ́ iṣẹ ìsìnlú.
Ọgbẹni Katung sọ eléyìí nibi ayẹyẹ ẹlẹ́bùn àlàáfíà ati eko adari ati ifilole iwe tí Douye Diri to waye ni ilu Yenegoa, Olu ilu Bayelsa.
Ó tẹ́ẹ̀ siwaju láti sọ iṣẹ ribiribi ti gomina Diri ti se ni ipinlẹ náà nipa idagbasoke ìlú.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san