Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó Se Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Lórí Ìmọ́tótó Oúnjẹ Fún Àwọn Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Olùtajà
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti pinnu láti tẹ̀síwájú lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn olùtajà lórí ìmọ́tótó, ìpamọ́ ati síṣe akẹ́tọ̀ọ́ àwọn ohun jíjẹ lójúnà àti mú kí oúnjẹ pọ̀ yanturu
Arábìnrin Abisọla Olusanya tí ó jẹ́ kọmísọ́nà fún ètò ọ̀gbìn ní ìpínlẹ̀ Èkó ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ní Idi-Oro, Mushin, Ìpínlẹ̀ Èkó
Ó sàfihàn pàtàkì ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí yóò se àlékún ìmọ̀ òwò síṣe, ìmọ́tótó, ààbò àti ìlànà òwò ìgbàlódé fún àwọn ará ìlú