Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ènìyàn Ìpínlẹ̀ Èkó Fi Ariwo Ta Látàŕi Òògùn Ìdáàbò Bò Lásìkò Ìbálòpọ̀ Tí Ó Gbówó Lórí

206

Àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Èkò ti ké gbàjarè látàrí òògùn ìdáàbò bò tí ó gbówó lórí èyí tí ó le è fa ìtànkálẹ̀ àrùn àti àìrò-tẹ́lẹ̀ oyún

 

Níbi ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nu -wò tí ó wáyé ní àwọn ènìyàn ti fi èhónú hàn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ní ìlú Èkó wípé àwọn òògùn ìdáàbòbò lásìkò ìbálòpọ̀ ti gbówó lórí, èyí tí kò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ànfààní láti rà, tí ó sì mú ìbẹ̀rù-bojo gbilẹ̀ lọ́kàn àwọn ará ìlú láti bá ara wọn lòpọ̀

 

Kòsí tàbí-sùgbọ́n kankan nípa wípé àwọn ohun èlò ìdáàbò bò lásìkò ìbálòpọ̀ tí ó gbówó lórí yóò mú kí àrun ìbálòpọ̀ tàn kálẹ̀, tí oyún àìrò-tẹ́lẹ̀ sì tún le è wáyé

 

Comments are closed.

button