Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti gba esi àyẹ̀wò ohun tó ṣokùnfa ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù tó wáyé ni agbègbè Bódìjà ni ìlú Ìbàdàn.
Èsì àyẹ̀wò náà ni àwon ikọ̀ onímọ̀ ìṣegùn òyìnbó, ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò àti àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ni wọn gbé wá fún Gómìnà Makinde ni ọfiisi Gómìnà tó wà ní Agodi ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.
Nígbà tó n ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ẹni tíì ṣe Olùdámọ̀ràn pataki fún Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ Ààbò, Fatai Owoseni jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ẹni mẹta kan ni wọn tọka sí pé o lọ́wọ́ nínú bi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọjọ́ náà ṣe wáyé, nígbà tó sọ gbangba wí pé gbogbo wọn ni yóò fojú ba ilé ẹjọ́ ni ìbámu pẹ̀lú ìwádìí.
Bákan náà ni Owoseni fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àdúgbò tí ìsèlè ti wáyé kii ṣe Dejó Oyelese ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ n pèé bí kò ṣe àdúgbò Aderinola.
Owoseni tun fi kún àlàyé rẹ̀ pé irú ohun èlò ìbúgbàmù náà ni wọ́n pe ni “Water Gel Type Based Explosive” eléyìí tó bú nígbà ti ìnà mọ̀nà-mọ́ná sọnà gẹ́gẹ́ bí ẹrọ to n ká ìṣẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ (CCTV) ṣe fìdí bi ìbúgbàmù náà ṣe wáyé múlẹ̀.
O wá tẹnu mọ pé ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò fi ojú ẹni ti ajere ìṣẹ̀lẹ̀ naa ṣí mọ́ lórí bá ilé ẹjọ́, àti pé Ìjọba yóò ṣe àyẹ̀wò ìwé ìgbélùú gbogbo àwọn èèyàn tí wọn fojú sùn nígbà to jẹ́ wí pé Orílẹ̀ èdè Málì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ won ti wà.
Àwọn akọsilẹ àdánù ti ìjàmbá náà ṣokunfa ni àdánù emi, ìfarapa onírúurú, ilé to dàwó lulẹ̀ àti àwọn tó wọnú ilẹ̀ lọ àti àwọn ilé tí ohun èlò iṣelọṣọ rẹ bajẹ náà ni wọn ti se àkọsílẹ rẹ.
Owoseni tún sọ̀rọ̀ nipa Àṣẹ láti òkè eléyìí tí gomina bu ontẹ lù lórí ona to yẹ láti máa ṣe àmúlò àti fífi àwọn ohun èlò alágbára pamó, nígbà tó tẹnu mọ pé olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó bá mọ pé ohun èlò alágbára to lè ṣokùnfa ìbúgbàmù wa ní àdúgbò wọn gbọdọ fi to ìjọba létí ni ilé iṣẹ́ ìjọba tó wà ní No 2, Oba Akenzua Crescent, Onireke, Ìbàdàn, tàbí ki wọn fi àtèjíṣẹ́ ránṣẹ́ sí itakun ayélujára yìí, declarenow@oyostate.gov.ng.
Abiola Olowe
Ibàdàn