Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti daro pẹlu ẹbi Ojougboh, ijọba ati awọn eniyan ipinlẹ Delta State Gusu Naijiria fun iku Dokita Cairo Ojougboh, Adari Alaṣẹ igbimọ idagbasoke Niger Delta (NDDC), nigba kan rí.
Ninu alaye kan ti agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale, buwọlu aarẹ sọ pe iroyin iku Cairo Ojougboh ba oun lojiji, ti o si ba oun ninu jẹ.
Nigba ti o n gbadura pe ki ọlọrun gbabọ ẹni ti o da gbere faye, aarẹ Tinubu wa rọ ẹbi Ojougboh lati mọkan, ki wọn o si gba fọlọrun.
Aarẹ tun wa fun ẹbi oloogbe naa nimọran lati jẹ ki inu wọn dun lori iranti ati awọn ohun ti agba oṣelu APC naa ti ṣe silẹ.
Dokita Ojougboh fi igba kan jẹ ọmọ ile igbimọ Aṣoju (2003–2007) ati adari ẹgbe oṣelu All Progressives Congress (APC) ni ipinlẹ Delta State.
Cairo Ojougboh jẹ Dokita iṣeegun ti o di oloṣelu ati olutaja, wọn bi ni ọjọ kẹjọ, osu kẹsan an, 1959, ni ijọba ibilẹ Gusu Ika ni ipinlẹ Delta, ti o si jẹ ẹya Agbor.