Orílẹ̀-èdè Burkina Faso Di Orílẹ̀-èdè Áfíríkà Kejì Ti Ó Fàyè Gbà Ògùn Abẹrẹ Ajẹsara Ti Àisìán Ibà Fún Àwọn Ọmọdé.
Láìpẹ́ yìí ni Orílẹ̀-èdè Burkina Faso di Orílẹ̀-èdè Áfíríkà Kejì tí o pàṣẹ pé kí wọn mú ògùn àisìán iba abẹrẹ ajẹsara wọ ètò abẹrẹ ajẹsara fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.
Orílẹ̀-èdè náà ti Kéde ògùn àisìán iba náà ti wọn pè RTS,S, sí àwọn àgbègbè ketadinlogbon ilé ìwòsàn ijoba ti o wa ni Orílẹ̀-èdè náà ti di tí bẹrẹ̀ lori rẹ.
Àjọ àgbáyé fún ètò ìlera (WHO) fi ontẹ lu abẹrẹ ajẹsara náà ni ọdún méjì sẹyìn, wọn ni abẹrẹ ajẹsara yìí yóò ṣe ọpọlọpọ iṣẹ lara àwọn èwe ni ile ìwòsàn gbogbo.
Wọn ni ṣugbọn pẹ̀lú abẹrẹ ajẹsara náà àwọn òbí yóò sì nilo, àwọ̀n ẹ̀fọn ati ògùn ti pa ẹ̀fọn láti ba leè Tunbo dènà àisìán iba yìí káàkiri.
Wọn ni àisìán iba jẹ eyi ti o buru ju ti kò sí bá àgọ́ ará mú rárá, wọn ni o yara lati gbà èmí pàápàá jùlọ láàrin ọmọde ati aláboyún
Wọn ni àwọn àmì ti yóò má farahàn ni orí fifọ, ọ̀túntùn, ará gbígbóná ati bẹbẹ lọ.
Orílẹ̀-èdè Cameroon ni Orílẹ̀-èdè àkókò tí ó bere ètò abẹrẹ ajẹsara náà ni ọjọ́ kejidinlogun oṣù kínní ọdún yìí.